O si mu gbogbo won ati kekere ati nla oloro ati talaka, ominira ati eru, ki a fi ami kan fun won ni owo otun tabi ni iwaju won. Ati ki enikeni ma le ra tabi ta, bikose eniti o ba ni ami oruko eranko naa tabi iye oruko re. Nihin ni ogbon gbe wa, eni ti o ba ni oye ki o siro iye ti n be lara eranko naa, nitori iye eniyan ni iye naa si je ota le legbeta o le mefa.666 (Ifihan 13:16-18)
666 JE ETO AKOSO GBOGBO AGBAYE LABE IJOBA KAN SOSO
Ni bayi,. Awon ohun elo kan to n sise pelu ero ayara bi asa (konputa) to le se ise odiwon ni a ti sise lori re ti awujo wa si ti gba wole. Ohun elo kekere ti a n lo pelu konputa ti n lo imo ero ni a ti fi sinu awon ohun elo ti n lo ina, awon oja tita, awon nnkan osin ati eniyan. Eyi kii se imo sayensi ti ojo ola ti ko le sele, o n sele lonii.
Ni opolopo ibi ninu aye, imo ti n lo ohun elo kekere kan lati se awari aisan, arun opolo, ito suga, aisan ninu okan, ti o si tun n dena eniyan jiji gbe. Ni aipe, iru awon ohun to nii se pelu emi yii yoo di ohun ti gbogbo aye fe won yoo si fee maa gbe e sara fun idanimo, aabo ati itopinpin. eto oro aje ati awon iwulo ti a ko tii le ronu re.
O se ni laanu pe iru awon ohun elo yii maa n toju ohun idanimo enikan, awon ohun ti a si ri mu jade ninu lilo re ni a le fi pamo ki a si je ki o wa ninu ero ayara bi asa. Ara eniyan a wa di eyi ti a se ami si ti a si n topinpin re, ti a o si maa dari iwa iru eni bee.
Gbingbin ohun elo (microchip) si ara eniyan yoo yi iri eniyan, irorun re ati igbe aye eni bee pada. Wahala to n waye nipa lilo ohun elo to ni se pelu emi lara eniyan koja oro ewa, ilera, eto iselu tabi oro ofin.
Satani n sise ninu aye, o si n yi awon eniyan pada lati mu ipinnu re se. Boya a mo tabi a ko mo, asodi si Kristi yoo fi ipa mu awon eniyan lati tele e ati lati gboran si agbekale to dabii pe o wa fun anfani awon eniyan oun sugbon ni titele igbekale itan aye eniyan ati iselodi eniyan si Olorun yoo mu irora ati ijiya wa titi ti Kristi yoo fi pada wa.
O si n tan awon ti n gbe ori ile aye je nipa awon ohun iyanu ti a fi fun wa lati se niwaju eranko naa, o n wi fun awon ti n gbe ori ile aye lati ya aworan fun eranko naa ti o ti gba ogbe ida ti o si ye. A si fi fun un lati fie mi fun awon eranko naa ki o ma a soro ki o si mu ki a pa gbogbo awon ti ko foribale fun aworan eranko naa (Ifihan 13:14-15)
Asiko kan n bo nigba ti awujo ati awon eniyan yoo wa ni abe akoso ara eni ti a o ti maa topinpin eniyan ti a o si maa se alaye re, a o maa se odiwon re, ti ero ayara bi asa (konputa) yoo si maa se ayewo re. Ni gba yii, enikeni ti o ba ko lati gba ilana yii ni a o fi iya je, ti a o si pa.
IDASILE AWUJO TI O WOPO
A ti n lo si ipele awujo ti o bara mu, ti awon eniyan ni ipokipo yoo ti ni anfani si ohunkohun nibikibi ati nigbakugba lai ni fi se asiko tabi ibi ti won wa. Lilo imo ero ti n fi ise redio han ni awon ile itaja kekere je apeere kan .
Ohun ti o n ti idagbasoke yii leyinn ni pe a o maa gbe igbe aye ti ko lewu, igbe aye to rorun, to ni oro ti o si se e gbadun nipa lilo imo ero to n sakoso igbe aye eni lojoojumo. Ni awujo to n pongbe fun eto isuna ti ero n sakoso re, ibara eni soro to ya kankan ati aabo, kii wa se ohun to le pe ti a o fi gba ki a fi ero to n sise pelu pelu radio si ni lara ti yoo si da owo ti a ti ji pada, tabi ti o sonu tabi eyi ti a pamo. Ni aipe ojo.
1. A o maa reti ki gbogbo eniyan ni ohun elo to n sise pelu emi. Gbogbo eto oro aje ni yoo maa lo ohun elo yii ti yoo si maa dipo bi a se n sewo.
2. Ko ni si ohun kankan ti o pamo mo, ominira ko si ni si mo.
3. Aladari kan ti o je asodi si Kristi yoo maa dari gbogbo aye nipa eto ti o je alatagba ti o si n kan ara won.
AMI ERANKO NAA NI ARA ENIYAN, A KO GBODO GBA A (Ifihan 14:9, 14:11, 16:2)
1. Gbigba ami yii je tita okan ara eni fun satani lai ni le ra a pada. Ese yii je eyi ti ko ni idariji, ti ko si se e yipada nipa ami naa (Ifihan 14:9-11) Olorun lo ni okan re. Nitori naa ti o ba gba ami yii, o ti di ti satani niyen.
2. Ti o ba gba ami yii, o n fi tifetife fi igbagbo re fun eniyan lai se Olorun. O ti yan lati gbe lai si Olorun ife to ni ipinnu lati lo ayeraye pelu re ni orun. Olorun ko fe ki o yan ona orun apadi. Olorun mo awon nnkan yii tele nitori pe o fe o, ti o si fe ki o mo eyi, a fi han wa ninu akosile Aposteli Johanu ninu iwe Ifihan ni ogorun odun leyin iku Kristi. Ti a ko ba mu o lo si orun ti a fi o sile fun ijiya, o ko gbodo gba ami eranko naa sibe a o je o niya, a o si pa o fun aigba ijoba ti satani n ddari re. O gbodo maa ranti eyi ni gbogbo igba nitori pe ireti orun si wa titi ti opin yoo fi de.
NJE O TI GBA JESU GEGE BI OLUGBALA RE?
Gbogbo eniyan lo sa a ti se ti won si kuna ogo Olorun (Romu 3:23)
Owo ko ni ohun gbogbo, eniyan ko le wa sodo Olorun nipa gbigbagbo ninu awon Olorun miran tabi igbekele eniyan, imo tabi rere sise. Ajosep[o pelu Jesu Kristi nikan lo le mu ki o se e se lati duro ninu ododo niwaju Olorun Mimo ni opin aye eniyan. Nitori idi eyi ni Jesu Kristi se jiya lori igi agbelebu, ti o ta eje re sile, ti o ku ti o si ji pada. Eleyi ni Olorun se lati fi ife re, agbara re ati ogo re nipa gbigba wa lowo ese ati iku.
Emi ni ona otito ati iye ko si eni ti o le wa si odo baba bi ko se ni pase mi (Johannu 14:6). Pe bi iwo ba fi enu re jewo Jesu ni Oluwa, ti iwo si gbagbo ninu okan re pe Oluwa jii dide kuro ninu oku, a o gba o la. Nitori okan li a fi a fi igbagbo si ododo, enu li a si fi ijewo si igbala. (Romu 10:9-10)
O gbodo gba Jesu gbo pe o ku fun ese re Jesu fe o niori ti Olorun fe araye to bee ge ti o fi omo bibi re kan soso fun ni ki enikeni ti o ba gba gbo ma baa segbe sugbon ki o le ni iye ainipekun. (Johannu 3:16). Ri ara re bi elese ki o si gbadura ninu igbagbo . O nilo lati gba Jesu ni olugbala re. Dajudaju orun wa, orun apaadi si wa. Jesu nikan ni ona si orun.
JESU N PADA BO MURA SILE FUN IGBASOKE
Jesu, eni ti o ra wa pada nipa agbelebu yoo pese ibi kan , yoo si pada wa lati wa pelu wa. O ti se ileri fun wa (Johannu 14:3) igbasoke yoo waye saaju wakati idanwo (Ifihan 3:10) Jesu wipe eyin le moye oju orun ati ti aye, sugbon eyin ko mo awon ami akoko wonyi (Mat. 16:3, Luku 12:56)
EYIN ARA MIMO NINU JESU KRISTI
Igbasoke je ohun ti a fi sile fun awon mimo ti a o gbe soke ni awosanmo nigba ti Olorun ba pe ipe, awon mimo ti a o gba soke ni a o gbe soke lati pade Jesu ni oju orun (1 Tessalonika 4:16-17) Igbasoke ni a fi sile fun awon onigbagbo ti o wo aso funfun ti emi. Ara won ni a o yi pada si ara ti ologo, yoo si je inu didun Oluwa. (Ifihan 19:7-8)
Ti o ba si wa ninu igbagbo ko gbona, ko tutu, Jesu yoo po o jade o ko gbodo dabi iru onigbagbo bi eyi (Ifihan 3:16) Wiwa Jesu akoko ni lati mu igbala wa, sugbon o n pada bo lati pade awon to se tan ti won si n duro dee ni awosanmo ni idahun si ipe, eyi ni a n pe ni igbasoke. Jesu Oluwa, yoo ko awon omo re pelu ara re lo si orun.Leyin wakati idanwo ninu aye, yoo tun pada wa si aye pelu awon ti a gba soke pelu re lo si orun lati lo si Jerusalemu titun, eyi ni a o pe ni Ipadabo re leekeji. Nitori kini ireti wa tabi ayo wa tabi ade isogo re? (1 Tessalonika 2:19)
Nigba ti Jesu ba pada de, awon eni mimo ti a gba soke nikan ni a o ko de iwaju ite ogo (1korinti 15:49-55). Bi a ti ko tile mo ojo ati asiko pipada bo re awon omo imole ko si ninu okunkun nitori naa ojo naa ko ni de ba yin bi ole. (1 Tessalonika 5:1-4). Nitori naa ranti bi iwo ti gba ati bi iwo ti gbo, ki o si pa a mo ki o si ronu piwada. Nje bi iwo ko ba sora, emi o de si o bi ole, iwo ki yoo si mo wakati ti emi o de si o. (Ifihan 3:3) Awon onigbagbo ko gbona ko tutu, awon ti a ti so mo aye ati awon ti ko mo Jesu ni a o fi sile fun wakati idanwo. Wakati idanwo yoo je igba eru julo ninu itan aye eniyan. Awon ti a fi sile ninu wakati idanwo ko gbodo gba ohun elo ti o ni se pelu emi (ti o ni oruko satani) si ara won (iwaju tabi owo otun Ifihan 13:16, 20:4) a ni de oju iku paapaa. Awon Kristeni to ba pa ara won yoo wa ninu ina titi ayeraye. Nipa kiko ohun elo yii, a o je o niya, a o si pa o fun awon alaigbagbo, kii se pe ki o ko ohun elo naa nikan, sugbon o nilati jewo Jesu ni Oluwa ati Olugbala re pelu enu re, ki o toro fun idariji fun ese re ki o si gbagbo ninu okan re pe omo Olorun ni ati pe o ku fun wa. Amin.
출처 : 천국은 확실히 있다
글쓴이 : goldface 원글보기
메모 :
'베리칩·1 > 베리 칩' 카테고리의 다른 글
[스크랩] 9.28긴급메시지(짐승의표666)-하우사어(서아프리카 무슬림 언어) (0) | 2015.12.17 |
---|---|
[스크랩] 9.28긴급메시지(짐승의표666)-필리핀 타갈로그어 (0) | 2015.12.17 |
[스크랩] 9.28긴급메시지(짐승의표666)-인도네시아어 (0) | 2015.12.17 |
[스크랩] 9.28긴급메시지(짐승의표666)-중국어(수정보완) (0) | 2015.12.17 |
[스크랩] 9.28긴급메시지(짐승의표666)-영어원문 (0) | 2015.12.17 |